Awọn ọmọ igbimọ alaṣẹ ipinlẹ Ọṣun ti sọ pe irọ to jinna sootọ ni ahesọ kan to n lọ kaakiri bayii pe o ṣee ṣe ki Gomina Ademọla Adeleke maa ṣeto labẹnu lati fi ẹgbẹ oṣelu PDP silẹ lọ sinu ẹgbẹ APC.
Nibi ipade oniroyin kan to waye niluu Oṣogbo lọjọ Mọnde ọṣẹ yii ni wọn ti sọ pe digbi ni Adeleke wa ninu ẹgbẹ PDP, bẹẹ ni awọn naa si duro wamuwamu bii ọmọ ogun lẹyin rẹ.
Akọwe wọn, Hon. Doṣu Babatunde ṣalaye pe ẹni ti ko ba nironu ni yoo fi ẹgbẹ PDP to ti ṣe awọn nnkan ara meriiri fun awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun laarin ọdun meji aabọ silẹ, ti yoo ni ẹgbẹ APC to mu ifasẹyin ba ilu loun yoo lọ.
O ni ko sigba kankan ti Adeleke n gba a lero lati fi ẹgbẹ PDP to gbe e dori aleefa silẹ, ipinnu rẹ si ni lati tẹ siwaju ninu oniruuru iṣẹ idagbasoke to n ṣe nipinlẹ Ọṣun, irọrun si ni saa keji rẹ ba de lọdun 2026.
Nipa ti awọn ti wọn n kuro ninu ẹgbẹ naa bọ sinu ẹgbẹ APC, Babatunde ṣalaye pe perete ni wọn, ko si si ohun ti wọn le ṣe lati dena saa keji fun Adeleke.
No comments:
Post a Comment