Pẹlu bi wahala iṣekupani ṣe n fojoojumọ gbilẹ sii, paapaa ni apa Guusu orileede yii, Wolii Sam Olu Alọ ti ke si ijọba apapọ lati ra oniruuru nnkan ija ogun to ba ti ode oni mu fun awọn ọmọ ileeṣẹ ologun ilẹ wa lati ṣẹgun wahala yii.
Ninu atẹjade kan to fi ranṣẹ si Gbagede ni ojiṣẹ Ọlọrun yii ti sọ pe adiyẹ awọn oṣiṣẹ alaabo ilẹ wa n laagun, iyẹ ni ko jẹ ki awọn araalu ri i.
O ni ohun ti wọn n koju ti wọn ba fẹẹ doju kọ awọn ikọ afẹmiṣofo yii lagbara ju nnkan ija ti wọn gbe lọwọ lọ, nitori idi eyi lo fi ke sijọba lati pese oniruuru irinṣẹ igbalode fun wọn.
Oludasilẹ ijọ CAC, Adamimogo, Grace of Mercy Power Mountain Worldwide ọhun tun ke si awọn ti ori sẹgi ọla fun lati kin ijọba lọwọ lori ipese irinṣẹ fun awọn agbofinro, ki alaafia kikun le wa kaakiri orileede Naijiria.
O ni loootọ nijọba n gbiyanju, ṣugbọn bi awọn afẹmiṣofo ṣe n pa awọn alaiṣẹ lojoojumo yii ko bojumu rara.
Pasitọ yii tun kilọ fun awọn ọdọ lorileede yii lati yago fun iwa wiwa owo lọna aitọ, o ni ibanujẹ pupọ lo jẹ lati gbọ nipa obitibiti owo ti awọn ọmọ Naijiria padanu sinuu sogundogoji CBEX laipẹ yii.
O ni pẹlu bi awọn araalu ṣe n pariwo pe ko si owo, nibo ni wọn ti ri owo ti wọn ko sorii CBEX eleyii to wọgbo-atuuu lọsan gangan.
Sam Olu Alọ tẹ siwaju pe kijọba apapọ gbiyanju sii lati ṣeto igbe aye irọrun fun awọn ọmọ orileede yii.
No comments:
Post a Comment