Afaimo ko ma je pe ibi ti Ooni ana Oba Sijuwade Olubuse ati Owa tilu Ilesa, Oba Adekunle Aromolaran fi aigbora-eni-ye won ti si naa ni Ooni tuntun, Enitan Ogunwusi yoo tun ti gbe e.
Iwadi fi han pe ko si irepo to lo titi laarin Olubuse ati Owa, wahala naa ko si seyin emi ju o, iwo o ju mi. Sijuwade ni alaga igbimo awon lobaloba nipinle Osun, nigba ti Owa je igbakeji.
Ni kete ti Ooni Sijuwade waja ninu osu keje odun yii ni Owa ti bere sii pe araa re ni alaga igbmo awon lobaloba bo tile je pe opolopo nigbagbo pe oye naa jinna si Ile Ijesa lopolopo ti won ba n fi bi awon omo Obatala se waye pin in.
Koda, Owa Aromolaran tun sekede ninu iwe iroyin kan nipa iku Ooni, to si pe araa re ni adele-alaga igbimo lobaloba l'Osun, bee lo je pe ti won ba wa nibi ayeye, se ni won maa n fii han gege bii alaga.
A gbo pe eleyii ko dun mo opolopo awon lobaloba ti won ni imo kikun nipa asa ati isedale Yoruba ninu rara, won gbagbo pe ipo naa ko lee kuro nilu Ileefe gege bii orirun ile Yoruba lapapo ati pe Owarangun ti ile Ila gan an saaju Owa Obokun ti won ba n soro nipa adele Ooni nibikibi.
Ni kete ti ijoba kede Ooni Ogunwusi lose meji seyin lawon eeyan ti n reti pe ki nnkan yipada si bo se wa tele, ki Owa si dekun lati maa pe araa re ni alaga igbimo lobaloba sugbon oro ko ri bee.
Lose to koja ni awon lobaloba nipinle Osun sepade kan nibudo asa ile adulawo to wa nilu Osogbo, nigba tawon oniroyin beere lowo Owa pe nigba wo lo di alaga igbimo awon lobaloba ati pe se yoo gbe oye naa sile ti Ooni Ogunwusi ba ti gbade, esi to fo ni pe awon oba kan ni won so oun di alaga won.
Owa ni "emi ko ni mo fi araa mi se alaga, awon lobaloba nipinle Osun ni won yan mi, nigba ti Ooni Sijuwade wa laye gan an emi ni mo n sise to po ju, ipo yii kii se eyi tenikeni maa n du, eyin naa si ri pe gboingboin lawon lobaloba wa leyin mi pelu bi won se wa sipade yii"
Sugbon ni kete ti Owa soro tan ni oba kan toun naa loruko dide lo sodoo re, to si so fun kabiesi pe "E ma wa ota kun ota o, Ooni tuntun ti de o........", bee lawon oba miin naa n mi ori layi le fi aidunnu won han si ohun ti Owa so.
Ti oro ba wa n lo bayii, ko seni ti yoo mo iha ti Ooni Ogunwusi yoo ko sii nitori pe enikan kii fi ii ti won ba pe lori te ile nilana Yoruba.
Tuesday, 10 November 2015
Wahala n bo lori oro ipo loba-loba nipinle Osun
.Unknown
.
Subscribe to:
Post Comments (Atom)

No comments:
Post a Comment