Ọtunba Iyiọla Omiṣore ti ṣeleri pe ọdun Ọlọjọ to maa n waye niluu Ileefẹ lọdọọdun yoo di ibudo isẹmbaye ti Ajọ Agbaye yoo fọwọ si ti oun ba ti di gomina ipinlẹ Ọṣun.
Omiṣore, ọkan pataki lara awọn to ti fi erongba wọn han lati dupo gomina ipinlẹ Ọṣun labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, ṣalaye pe Ọlọjọ jẹ ọdun to ti gbajugbaja kaakiri agbaye, ko si si nnkan to ni ki Ajọ Agbaye ma ti i fọwọ si i.
Nibi ayẹyẹ ọdun Ọlọjọ to waye lọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu Kẹsan ọdun yii ni gbagede aafin Ọọniriṣa ni Omiṣore ti gboṣuba fun Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi fun akitiyan rẹ lati pa aṣa ati iṣe ilu Ileefẹ mọ.
O ni ilu ti Eledua fi oniruuru aṣa jinki ni ilu Ileefẹ, idi si niyẹn to fi wa ninu erongba oun pe ọdun naa yoo di ibudo Isẹmbaye gẹgẹ bii Ọṣun Oṣogbo.
Lara ohun to waye nibi ayẹyẹ naa ni bi Ọọni Adeyẹye ṣe de ade Are, eyi ti gbogbo Yoruba nigbagbọ pe Oduduwa de nigba aye rẹ, lọ si Okemogun nibi to ti sure fun gbogbo awọn ọmọ Oodua.
No comments:
Post a Comment