Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ, NULGE, ẹka tipinlẹ Ọṣun ti ke gbajare pe ijọba apapọ ti san owo oṣu mẹfa fun awọn alaga ati kanselọ to jẹ ti ẹgbẹ osẹlu APC.
Nibi ipade oniroyin kan to waye niluu Oṣogbo lọjọ Sannde, ọjọ kejidinlọgbọn oṣu kẹsan ni wọn ti sọ pe iwa naa lodi si ofin orileede yii.
Alaga wọn, Ogungbangbe sọ pe o ya awọn lẹnu pe wọn ti sanwo naa sinu akanti UBA ti awọn APC ṣi, nigba ti wọn mọ pe ile ẹjọ ti yọ wọn kuro.
Wọn ṣeleri pe awọn ko nii ba awọn alaga naa ṣiṣẹ lailai.
Ẹkunrẹrẹ nbọ laipẹ..
No comments:
Post a Comment