IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 26 September 2017

Egbe awon dokita nipinle Osun soko oro sigbakeji gomina

Tolulope Emmanuel, Osogbo

Egbe awon dokita oyinbo nipinle Osun, Nigeria Medical Association ti sapejuwe oro kan tigbakeji gomina ipinle Osun, Otunba Grace Titi-Laoye Tomori so laipe yii gege bi eyi to ku die kaato.
Ninu atejade kan ti alaga egbe naa, Dokita Tokunbo Olajumoke ati akowe re, Olalekan Ajayi fowosi ni won ti ni ibanilorukoje lasan loro naa.
Ojo kejidinlogun osu kesan odun yii lawon omo egbe naa bere iyanselodi nipinle Osun latari ipo aibojumu tawon ileewosan wa nipinle Osun ati bijoba se kuna lati san ekunrere owo osu ati ajemonu won.
Sugbon nibi ayeye kan ni won ni igbakeji gomina ti so laipe yii pe kii se awon dokita nikan losise ijoba nipinle Osun ati pe ijoba ko lee torii pe o fe te won lorun yan awon osise ijoba to ku niposin.
Sugbon egbe NMA ni igbakeji gomina ko so otito rara, o kan n gbiyanju lati ba egbe naa lorukoje loju awon araalu ni.
NMA ni oro tijoba apapo so laipe yii ninu eyi to ti ka ipinle Osun mo awon ipinle to kuna lati sanwo awon osise bo tile je pe obitibiti owo nijoba apapo ti ko fun won sapejuwe ijoba ipinle Osun gege bi eyi ti ko kunju osunwon.
Egbe naa waa ro gbogbo awon omo egbe lati pada senu isee won latari bi opolopo awon lookolooko se ti ba won sepade lori iyanselodi naa.
Egbe naa ni awon yoo pada senu ise lati wo igbese tijoba fee gbe lori oro awon.

1 comment:

  1. Oro sunukun, oju sunukun lafi wo, afi k'Olorun sanu wa

    ReplyDelete