Adeola Tijani
Ijoba ipinle Oyo ti kede pe ki ibudo ti won n toju awon eranko si, iyen Zoo to wa nilu Ibadan wa ni titipa fungba die.
Igbese yii ko seyin bi okan lara awon kiniun to wa nibe tele doju ija ko baba kan to n mojuto ogba naa, tiyen si pada ku.
Baba naa, Ogbeni Hamzat Oyekunle ti gbogbo eeyan mo si Baba Olohunwa la gbo pe o ti pe to ti wa pelu awon eranko inu ogba naa.
Ileese AM&C to n mojuto ogba naa funjoba ipinle Oyo la gbo pe o gba Baba Olohunwa sise kisele naa too sele.
Idi niyii tijoba fi ko gbogbo awon kiniun ti won wa logba naa kuro bayii, ti won si pase pe ki ogba ohun wa ni titipa fun saa yii na.
No comments:
Post a Comment