IROYIN YAJOYAJO

Sunday, 1 October 2017

Igboraeniye nikan lo le mu alaafia wa lorileede yii - K-Rad

Tolulope Emmanuel, Osogbo

Oludasile egbe Tiwa n Tiwa l'Osun, Ogbeni Kunle Adegoke ti gbogbo eeyan mo si K-Rad ti ki gbogbo awon omo orileede Naijiria ku oriire ayajo odun ketadinlogota ti orileede yii gbominira lowo awon oyinbo amunisin. 

K-Rad, eni to n gbaradi lati dije funpo gomina ipinle Osun labe asia egbe oselu APC salaye pe ayajo oni je eyi ti gbogbo awon omo orileede yii gbodo lo lati fi wo ibi ti a ti n bo, ibi ti a de duro ati ibi ti a n lo. 

Okunrin agbejoro yii ni ife ati isokan nikansoso lawon omo orileede yii nilo fun idagbasoke tonikaluku n reti ati pe igboraeniye nikan lo le mu ki alaafia wa laarin eleyameya lorileede yii. 

Adegoke ro gbogbo awon eeyan orileede yii paapa awon omo ipinle Osun lati fowosowopo pelu ijoba ni eka gbogbo ki ilosiwaju le ba agbegbe kookan. 

O waa ro gbogbo awon omo egbe oselu APC nipinle Osun lati mase ri idibo to n bo gege bii bo o ba o pa, bo o ba o buu lese. O ni ki won yago fun ipolongo onilara sugbon ki won setan lati gba enikeni ti Olorun ba yan lati gbe ipinle Osun doke tente. 

1 comment: