IROYIN YAJOYAJO

Saturday, 30 September 2017

Alawada lasan ni Fayose, alainikanse si ni pelu -Buruji Kasamu



Seun Ajibade, Abeokuta

Seneto to n soju awon eeyan agbegbe Ila-oorun Ogun nile igbimo asofin agba orileede yii, Kasamu Buruji ti so pe awada kerikeri ni erongba okan gomina ipinle Ekiti, Dokita Ayodele Fayose lati di aare orileede yii lodun 2019.

Kasamu, eni toun naa je omo egbe oselu PDP ni oun ti n ri eni ti ko see fokantan laye, ti Fayose tun yato.

O ni bawo ni Gomina Fayose to wa nijoko lasiko tawon agbaagba egbe n so pe iha Ariwa orileede yii ni oludije funpo aare latinu egbe naa yoo ti wa yoo tun se jade so pe oun nife lati dupo naa.

O ni iwa alainikanse ati eni ti ko mo nnkan to ku loroo re ni Fayose hu ohun ati pe ala lasan ti ko le wa simuse ni.

A oo ranti pe lojo melo seyin ni Fayose lo silu Abuja lati loo kede erongba re lati di aare orileede yii lodun 2019.


1 comment:

  1. Sibe sibe, Olorun lomo oun gbogbo tosi lese oun gbogbo

    ReplyDelete