Adeola Tijani
Agbola Ibrahim, omo odun metalelogun ladajo agba majistreeti kan nilu Ibadan ti ni ki won na ni koboko mejila niwaju ita kootu lori esun ole jija.
Mansinni Bajaj tuntun kan ti oninnkan o tii gba nomba si la gbo pe Ibrahim ji lojo ketalelogun osu kejo odun yii lagbegbe Mokola nilu Ibadan.
Nnkan aago meji osan ni agbejoro funleese olopa, Shalewa Hammed so pe Ibrahim ji okada ti owo re to egberun lona otalelugba naira ohun ati pe lasiko to n salo lowo ba a.
Shalewa ni iwa olujejo ohun lodi, bee lo si nijiya labe ofin iwa odaran tipinle Oyo ti odun 2000.
Ninu idajo adajo agba majistreeti kootu keji ni Iyaganku ohun, A. a. Adebisi, o pase pe ki won mu Ibrahim lo sita gbangba kootu ki won si na an ni koboko mejila to gbona. 
No comments:
Post a Comment