Tolulope Emmanuel
Leyin osu meji ti Seneto Mudashiru Hussein fidi remi ninu idibo sile igbimo asofin agba lati ropo Oloogbe Isiaka Adeleke, o ti pada bayii senu ise re gege bii komisanna l'Osun.
A oo ranti pe inu osu karun odun yii ni Gomina Aregbesola bura fun Hussein gege bii komisanna foro to nii se nipa awon igbimo alase ipinle Osun, sugbon nigba tasiko to lati fa oludije kale lati ropo Adeleke, Hussein kowe fipo sile.
Sugbon ninu idibo naa ni aburo Adeleke, Ademola ti gbewuro sojuu Hussein, ti iyen si di seneto.
Latigba naa lawon eeyan ti n so pe Hussein le ma pada gege bii komisanna, sugbon iyalenu lo je pe okunrin oloselu to ti fodun mejo je omo ile igbimo asofin apapo, to tun fodun merin se Seneto tun ti pada senu ise re bayii gege bii komisanna.
No comments:
Post a Comment