Gomina ipinle Imo, Rochas Okorocha ti so pe edun okan lo je fun oun bijoba Aare Mohammed Buhari se gbagbe ipa takuntakun toun ko saaju ati lasiko idibo apapo to waye lodun 2015 lorileede yii.
Okorocha ni ohun to buru ju nibe ni pe gomina ipinle Rivers tele, Rotimi Amaechi ti egbe oselu APC ko rowomu nipinle re gan an lo wa n gbadun ijoba bayii.
Lasiko tawon eeyan ijoba ibile Njaba sabewo sii fun ayeye ayajo odun karundinlogota to se ni Gomina ti so fawon eeyan ohun pe kii se pe oun n saroye o tori oun ti gba f'Olorun, oun si mo pe igba toun naa a de laipe, Aare Buhari yoo si ranti ipinle toun naa si rere.
O waa so pe kawon naa se suuru fun oun ati pe ise idagbasoke yoo de odo tiwon naa laipe.
Thursday, 28 September 2017
Okorocha kabamo, o ni ijoba Buhari ti gbagbe wahala oun lori egbe APC
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment