O kere tan, eeyan metadinlaadosan (167) lawon ajinigbe ti ji gbe nipinle Kogi laarin odun kan seyin bayii.
Gomina ipinle naa, Yahaya Bello lo soro naa lasiko ikekojade awon ti won sese gba sileese olopa nipinle Niger atipinle Kogi.
Bello ni oro ijinigbe sese n dinku nipinle Kogi ni latari bijoba se mu oro aabo lokunkundun bayii.
O ni teletele, gbogbo awon arinrinajo ni won maa n beru wiwa si ipinle Kogi tabi kikoja nibe gan an latari pe ojoojumo ni won maa n ji awon eeyan gbe sugbon to ni eleyii ti yato bayii.
Bello fi kun oro re pe oko aafojo loun ra lori ipese eto aabo fawon eeyan ipinle oun ati pe eeyan egberun meta loun ti gba sise fun ipese aabo, eleyii to mu kiyipada ba igbe aye awon araalu.
Gomina, eni ti oludamoran pataki re lori eto aabo, Commander Jerry Omodara (rtd) soju fun salaye pe laarin osu meje pere, awon ile mejidinlogun nijoba ti wo lule latari bi won se je ile awon ajinigbe.
Olorun ni kogbani lori awon iwa odaran gbogbo lorilede wa
ReplyDelete