Tolulope Emmanuel, Osogbo
Latari ewu to wa nibi fifi igbale ja ewedu, awon dokita ti pariwo bayii pe kawon araalu, paapa awon abiyamo jawo ninu asa naa.
Dokita Adegboyega Akere ti ile eko isegun oyinbo ti UCH nilu Ibadan lo soro yii.
O ni ewu nla to wa nibe ni pe opo igba lawon igbale kekeke ohun maa n ja sinuu ewedu laimo.
Akere ni teeyan ba wa lo seesi gbe iru igbale naa mi pelu ewedu, se lo maa duro sinu ona ofun tabi ko wonu ifun lo eleyii to ni ise abe nikan lo le gbe e jade.
Dokita yii waa ro gbogbo awon obinrin, paapa awon to je pe amala ati ewedu ni won fi maa n gba oyan lenu awon omo won lati dekun lilo ijabe.
O ni o san keeyan lo mansinni taa fi maa n we ata ninu ile (blender) tabi keeyan gun un bii ata ko too di pe yoo se e.
Friday, 29 September 2017
Won tun ti de o! Awon dokita ni ka ma figbale ja ewedu mo o
Tags
# iroyin
# iroyin-agbegbe
.Unknown
.
iroyin-agbegbe
Labels:
iroyin,
iroyin-agbegbe
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment