IROYIN YAJOYAJO

Saturday, 23 September 2017

Iyawo osingin! Kabiru Aregbesola segbeyawo alarinrin pelu Farida loni nilu Eko

Beeyan gesin ninuu gomina ipinle Osun, Ogbeni Rauf Aregbesola atiyawo re loni, o daju pe ko nii kose.
Oni yii gan an ni won sayeye igbeyawo alarinrin fun akobi won, Kabiru nilu Eko.
Inu osu karun odun yii ni idana waye laarin molebi Aregbesola ati Alli nilu Eko, nigba naa ni won si dajo Nikah siwaju di oni.
Faridah Alli loruko iyawo ti Gomina Aregbesola fe fun omo re ohun, opolopo awon lookolooko ni won si peju pese sibi ayeye alarinrin naa.
A oo ranti pe ko pe ti Gomina Aregbesola dori aleefa nigbeyawo kan waye laarin Kabiru ati omo Alhaja Ayo Omidiran sugbon ko seni to mo nnkan to sele sigbeyawo naa.

1 comment: