IROYIN YAJOYAJO

Saturday, 9 September 2017

Laisi eto eko to ye kooro, ko lee si ominira - Seneto Omoworaare

Seneto to n soju awon eeyan ekun idibo Ila-Oorun Ife nile igbimo asofin agba, Babajide Omoworaare ti gba awon odo niyanju lati fojusi eko won nitori pe ninuu re ni ominira won wa.
Omoworaare soro yii lasiko asekagba eko inu olude eleyii to seto fun awon akeko ti won to egberun merin lekun re.
Eto yii je ajose laarin Omoworaare ati awon egbe National Ife Descendants Students Association pelu awon lookolooko miin nilu Ileefe.
Omoworaare, eni ti Onorebu Olatunde Owojori soju fun salaye pe erongba eto naa ni lati rii pe awon akeko fimokunmo lasiko olude won dipo ki won maa rin kaakiri laisise kankan.
O dupe lowo awon NIDSA fun bi won se gba a laaye lati sisepo peluu won.
O waa ro awon akeko ohun lati mase je ki ohunkohun si ojuu won kuro lara ekoo won.
Ninu oro re, aare egbe NIDSA, Seun Agboguleri dupe lowoo Seneto Omoworaare atawon miin ti won lowo ninu aseyori eko inu olude naa, bee lo tun yin awon ti won wa nibi ayeye asekagba ohun lawo.
Leyin eyi ni won kede oruko awon akeko mejidinlogun ti won dangajia julo ti Seneto si fun won leko-ofe.
Bakannaa ni Omoworaare sanwo idanwo WAEC ati JAMB awon meta miin.

No comments:

Post a Comment