IROYIN YAJOYAJO

Thursday, 28 September 2017

Loooto onimo isegun oyinbo ni mi sugbon ise orin lori ran mi - Ajetunmobi

Tolulope Emmanuel

Omobibi ilu Ondo ni Dokita Abiola Ajetunmobi sugbon oke -okun lo fi sebugbe.

Bo  se je gbajugbaja onimo isegun lohun ni ko si enikeni to lee fowo ro o seyin ti a ba n soro nipa orin emi kiko.

Odun 1984 ni dokita ti Olorun fun lopolopo ebun yii bere ise orin kiko, latigba naa si nirawo re ti n tan laarin awon olorin emi loke -okun to wa.

Awo orin meji otooto ni omobinrin oniwa irele yii ti gbe jade, bee lo n sise lorii eyi to pe ni Grace and Mercy lowo.

Nigba to n soro lori idi ti ko fi gbajumo ise to fi gbogbo asiko re ko nileewe, Dokita Abiola ni ipe ti Olorun pe oun ni lati maa korin gbe e ga.

O ni oun tun n lo orin lati waasu ihinrere ati lati jere okan fun Olorun. O fi kun oro re pe latigba toun ti bere orin kiko yii, Olorun ko figbakankan ja oun kule ri.

No comments:

Post a Comment