IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 10 October 2017

Abenugan tele, Dimeji Bankole je loya lowo, lo ba foju bale ejo

Awon agbejoro ti won soju fun abenugan ile igbimo asofin apapo orileede yii tele, Onirebu Dimeji Bankole lasiko to n jejo pelu ajo EFCC ti wo o lo sile ejo bayii lori esun pe ko san owo ise fun won.

Awon agbejoro ohun, labe oruko ofiisi won, MJS  Partner ni won ni awon pelu Bankole jo se adehun  milioonu lona aadorin naira nigba naa sugbon to san milioonu meta pere.

Loruko awon olujejo, Dokita Yemi Oke so nile ejo giga Isabo nilu Abeokuta pe leyin ti ile ejo pase lodun 2013 pe ki olujejo san egberun meje fawon, sibe ko san owo naa eleyii to fa ti won tun fi pada sile ejo.


Agbejoro fun olujejo, Abiodun Aboaba bebe pe ki won foun lasiko perete lori ejo naa paapaa nipa awon nnkan ti olupejo ro mo ejo. O so pe oun sese ri gbogbo awon ti olupejo naa pe, oun si gbodo funra oun laye die lati ye e wo


Nigba ti Adajo Dipeolu  n soro, o ni ile ejo ko nii faaye gba enikeni lati maa fa ejo nile.  O waa sun igbejo siwaju di ojo ketadinlogun osu kewa yii.

1 comment: