IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 10 October 2017

O ma se o! Awon agbowo-ori pa Iya Ayo l'Akure, bee opo ni

Obinrin eni odun mejidinlogoji, Toyin Ijiyemi lawon agbowo-ori ti ran lo sorun osangangan nijoba ibile Guusu Akure bayii nitorii pe ko ri owo ori san.

Nnkan aago meji osan la gbo pe awon agbowo-ori naa ti won je merin niye de soobu obinrin ti gbogbo eeyan mo si Iya Ayo lagbegbe Bolajoko ni Oke-Aro, o si be won pe oun ko tii lanfaani lati ko owo naa jo nitori ko si iranlowo fun oun latibikankan.

Iya Ayo, eni to n sise aserunloso so fun won pe oun nikan loun n gbo bukata ile latigba ti oko oun ti ku lodun die seyin, sugbon gbogbo arowa yii la gbo pe ko wo won leti, bayii ni okan ninuu won gbe telifisan to wa ninuu soobu obinrin yii, asiko ti Iya Ayo n fa telifisan yii mo on lowo lo subu lule.

Awon agbowo ipa yii ko tie weyin, enikan to fee ra pio wota la gbo pe o ba Iya Ayo nileele nibi to ti n japoro iku, won gbe e lo sileewosan sugbon epa ko boro mo, obinrin yii jade laye.

Ni sekiteriati ijoba ibile naa la ti gbo pe awon olopa ti mu awon agbowo-ipa mereerin yii, bee ni omokansoso ti obinrin yii bi, Ayodele n pariwo pe kijoba se ohun to to lori oro naa ki iku iya oun ma baa ja si asan.

Alukooro ileese olopa ipinle Ondo, Femi Joseph fi idi isele naa mule, o ni owo ti te awon kan lori oro naa ati pe leyin iwadi ni won yoo foju bale ejo.

No comments:

Post a Comment