IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 10 October 2017

Ko si ise miin ti mo le se laye ju ki n gbin igbo lo - Augustine



Okunrin eni ogoji odun kan, Augustine Sanjay ti so pe leyin koun gbin igbo (Indian hemp), koun si ta a fawon ti won nilo re, ko si ise kankan toun tun le se mo.

Lasiko o n so nnkan to wa dedii igbo gbingbin nigba ti owo awon omo ajo to n gbogunti gbigbin ati lilo egbo igi oloro ti eka ipinle Ondo te Augustine lo so pe ko si ise kankan to pe bii ise naa.

Augustine ni niwon igba toun ko ti le jale tabi ki oun maa ji awon olowo gbe kaakiri bi awon odo akeegbe oun se n se lasiko yii, oun ko lee fi ise naa sile.

Okunrin naa, eni to ni ko si nnkan to buru ninu ise ti oun n se salaye pe ise to see mu yangan ni ise naa.

No comments:

Post a Comment