IROYIN YAJOYAJO

Wednesday, 4 October 2017

Bamigbade fi owo moto lu Helen ni jibiti milioonu kan naira l'Osogbo



Tolulope Emmanuel, Osogbo

Milioonu kan naira ti Arabinrin Helen Salako ko fun okunrin kan nilu Osogbo ti wogbo bayii nitori ko ri owo, bee ni ko fojukan moto ti won jo sadehun. 

Laarin osu karun si osu keje odun yii ni Helen fi da owo ohun jo sowoo Bamigbade Adedotun eni odun marundinlogoji pelu erongba pe o fee ta moto Toyota Corolla kan foun sugbon ti oro naa pada ja si jibiti. 

Gbogbo igbiyanju Helen lati gba owo naa pada lo ja si pabo, idi si niyii to fi loo fi oro naa to awon olopa leti. 

Nigba tawon olopa mu Bamigbade, o jewo pe loooto loun gba owo naa lowo Helen, bayii ni won taari re wa sile ejo majistreeti lati waa so ohun to ri lobe to fi waaro owo. 

Esun meje otooto ninu eyi ti a ti ri ole jija, jibiti lilu, didogbon gba owo, idite lati huwa ibi ati bee bee lo ni won fi kan Bamigbade. 

Asoju ileese olopa lori oro naa, Inspekito Elisha Olusegun ni lojule keta, zone 4 lagbegbe Rinsayo Estate nilu Osogbo nisele naa ti sele. 

O ni olujejo se si abala kerinlelogbon ofin iwa odaran tipinle Osun. 

Leyin ti Bamigbade ni oun ko jebi awon esun ti won fi kan an ni agbejoro re, Adeyinka Dada ro ile ejo lati faaye beeli sile fun un lona irorun pelu ileri pe ko nii salo fun igbejo. 

Sugbon kia ni asoju ileese olopa ti so pe okunrin olujejo naa yoo salo tile ejo ba gba beeli re. O ni se ni Bamigbade salo raurau nigba tawon olopa koko fii sile ko too wa di pe won tun rii mu. 

Ninu idajo re, Majistreeti Ashiru Ayeni faaye beeli sile fun olujejo pelu egberun lona eedegbeta naira ati oniduro meji ni iye kannaa. 

O waa sun igbejo siwaju di ojo keje osu kokanla odun yii.

No comments:

Post a Comment