IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 3 October 2017

Ko si nnkan to le ya emi ati Fayose - Femi Fani-Kayode



Tolulope Emmanuel, Osogbo

Minista tele feto irinna ofurufu lorileede yii, Femi Fani-Kayode (FFK) ti ni ooya kan ko lee ya oun ati gomina ipinle Ekiti, Dokita Ayodele Fayose nitori pe opolopo abuda lawon ni papo.

Gege bo se so "Fayose je akinkanju okunrin, kii beru, ko si le gba kenikeni ko o laya je  nibikibi. Ajafeto alailagbara ni, bee lo maa n so otito ponbele laika nnkan tenikeni le so si.

"A maa n ja o, bee ni erongba wa lori oniruuru nnkan maa n yato nigba miin, sugbon opolopo nnkan la ni papo. Orisun agbara re wa ninu Olorun bii temi naa.

"A feran Olorun, a si nigbagbo ninuu Re. Emi Dafidi ati Jehu wa lara wa, a ko beru ilu tabi afose kankan, a korira iyanje.

"O je omo Yoruba tooto to nigboya lati so pe oun fee dupo Aare orileede yii, o si ti sise takuntakun nipinle Ekiti, idi niyen ti ko fi beru lati so funjoba Buhari nipa awon nnkan ti ko bojumu to n sele laiberu".

No comments:

Post a Comment