Tolulope Emmanuel, Osogbo
Seneto to n soju awon eeyan agbegbe Ife/Ijesa nile igbimo asofin agba, Babajide Omoworaare ti so pe awon eeyan orileede yii gbodo fowosowopo pelu isejoba Aare Buhari ti a ba mo pe loooto la n fe idagbasoke.
Omoworaare ni ko seese lati tun pada sinu igbesi aye ti a n gbe lasiko isejoba to tabuku ba ogo orileede Naijiria.
Ninu oro ikini ku odun ominira orileede yii eleyii to fi ran akowe iroyin re, Babatunde Dairo ni Omoworaare ti ni iyato ti ba iwe aaro orileede yii latigba ti egbe oselu APC ti dori aleefa.
O ni ariwo atunto orileede yii tijoba apapo n pa je eri pataki to fi han pe isejoba to le mu orileede yii dele ileri lo wa nibe lowolowo.
Seneto yii fi kun oro re pe o pon dandan ki tolori -telemu gbaruku tijoba ka ma si se faaye gba enikeni lati da wa pada sinu isejoba jegudujera, isejoba aisi aabo to peye ati isejoba ti ko ni ife awon araalu lokan.
Omoworaare waa pe fun ife tooto laifi ti eya, esin tabi ede se ki orileede yii le maa tesiwaju ninu ise rere gbogbo.
No comments:
Post a Comment