Tolulope Emmanuel
Igbakeji oga agba nileese asobode ile wa nigbakanri, Omooba Francis Adenigba Fadahunsi ti so pe kawon omo orileede Naijiria mase soreti nu nipa orileede yii.
Lasiko isin idupe ayajo odun ketadinlogota ominira orileede yii eleyii to waye nilu abinibi re, Ilase lo ti soro yii.
Fadahunsi ni igba otun yoo si de ba orileede yii niwon igba tawon eeyan inu e ba ti mo eto won, ti won si n sise to o.
O ni asiko ti to fawon oludibo lati dekun tita ojo ola won ati tawon omo won fawon oloselu ti won kan n lo won lati de ori ipo.
Fadahunsi, eni to ti figba kan dupo sile igbimo asofin agba orileede yii labe asia egbe oselu PDP lekun Ife/Ijesa waa lo asiko naa lati tun ipinnu re se lorii mimu irorun igbesi aye awon eeyan re lokunkundun.
Asiko tito fun awa omo orilede Nigeria lati setan lati mu igba otun de lorilede yi
ReplyDelete