Tolulope Emmanuel, Osogbo
Omobinrin eni odun marundinlogoji kan, Nafisat Raji ladajo majistreeti ilu Osogbo ti ju sewon osu mefa bayii lori esun pe o ji komputa.
Sugbon adajo ohun, Adenike Olowolagba faaye faini egberun meta naira sile fun un gege bii owo itanran leyin to ti so pe oun jebi esun ti won fi kan oun.
Gege bi iwe ipejo Nafisat se salaye, ogbonjo osu kejo odun yii ni olujejo huwa naa lagbegbe Akeju nidojuko Government Technical College nilu Osogbo ni nnkan aago mokanla aabo ale.
Laptop HP towoo re to egberun lona arundinlaadota naira to je ti Ogbeni Mubarak Olaboopo lomobinrin yii koko ji lojo naa.
Leyin naa ni won ni Nafisat tun ji foonu kan to je ti Deborah Akindele lagbegbe Fayemi nilu Osogbo kannaa eleyii ti won ni owoo re to egberun lona merinla ataabo naira.
Asoju ileese olopa lori oro naa, Inspekito Joshua Oladoye ni iwa ti olujejo hu lodi, bee lo si nijiya nla labe ofin iwa odaran tipinle Osun ti odun 2003.
Sugbon nigba ti won ka ese Nafisat sii leti, se lo bu sekun regbede ninuu kootu, ko si fasiko sofo rara to fi ni oun jebi esun naa.
Agbejoro re, Nagite Okobie ni niwon igba ti Nafisa ti mo pe oun jebi esun naa, o to ki ile ejo siju aanu woo.
Ninu idajo re, Majistreeti Olowolagba ni ki Nafisa loo faso penpe roko oba fun osu mefa tabi ko san egberun meta naira gege bii faini re.
No comments:
Post a Comment