IROYIN YAJOYAJO

Monday, 16 October 2017

Eni to kunju osunwon ni Ojogbon Olatunde - OSAF




Tolulope Emmanuel, Osogbo

Egbe kan to n ri si igbeaye irorun awon omo ilu Osogbo nile ati leyin odi, Osogbo Affairs Forum (OSAF) ti gbe osuba kare fun gomina ipinle Ogun, Seneto Ibikunle Amosun fun bo se yan Ojogbon Ganiyu Olatunji Olatunde gege bii giwa Fasiti Olabisi Onabanjo.

Ninu atejade kan ti alaga ati akowe egbe naa, Omooba Hammed Oyegbade ati Barista Abdulrahman Okunade fi sita ni won ti juwe iyansipo Ojogbon Olatunde gege bii ika to to simu ti a fi re e.

Egbe OSAF ni eni to kaju e, to mo nnkan to n se, to si jafafa lenu ise ni Ojogbon omo ilu Osogbo naa ati pe Gomina Amosun ko nii kabamo bo se yan an.

Won ni iyipada alailegbe ni yoo ba fasiti ti won dasile lodun marundinlogoji seyin ohun lasiko yii ti Ojogbon Olatunde di giwa re nitori pe ko sibi ti okunrin naa de ti won kii mo igba re si rere.

OSAF ni pelu iriri Ojogbon ohun gege bii igbakeji giwa ni UNIOSUN ati adele giwa ni UNIOSUN bakannaa nigba kan ri, o daju pe oke tente ni eye fasiti  Olabisi Onabanjo yoo maa fohun laipe rara.

Won waa ki Ojogbon Olatunde ku oriire iyansipo naa, won si gbadura pe ki Olorun ran an lowo lati mase ja igbekele awon eeyan ninuu re kule.

No comments:

Post a Comment