Tolulope Emmanuel, Osogbo
Okunrin parakoyi onisowo to je omobibi ilu Ede nipinle Osun, Dokita Deji Adeleke ti so pe ko si ooto kankan ninu aheso tawon kan n so kaakiri pe oun fee dupo gomina ipinle Osun labe asia egbe oselu APC.
Ninu atejade kan ti Ogbeni Dele Adeleke ko loruko Deji Adeleke, o ni ise aanu ti Olorun ran dokita naa wa se laye lo gbajumo, ko si yojuran sinu oselu rara.
Deji Adeleke, eni to je baba fun omokunrin olorin nni, Davido, to si tun je oludasile Adeleke University nilu Ede lo ni oun ko figbakankan ronu e ri lati dupo gomina l'Osun.
Atejade naa waa ro gbogbo awon araalu lati ko eti ikun si aheso naa, ki won si mo pe idile Adeleke ko nii reyin ninu ise aanu ti won n se fawon araalu.
No comments:
Post a Comment