Tolulope Emmanuel, Osogbo
Komisanna feto ilera nipinle Osun, Dokita Kusamotu ti so pe oniruuru eto nijoba ti se sile lati le ri pe arun to n ja nile bayii ti won n pe ni Monkey Pox ko ridi joko nipinle Osun.
Lasiko to n ba awon oniroyin soro, Kusamotu ni yato si pe ijoba ti seto ibudo meta kale nibi ti won le maa gbe awon to ba ti lugbadi arun naa si funtoju, awon tun ti bere idanileko fawon onimo isegun oyinbo lori arun naa.
Komisanna yii fi kun oro re pe awon ko tii gburo arun ti won lo koko farahan lara awon obo (monkey) ohun nibikibi nipinle Osun.
O waa ro awon araalu lati mu imototo ayika won lokunkundun, bee ni ki won yago fun jije eran igbe lasiko yii.
A oo ranti pe laipe yii nijoba apapo orileede yii ni eeyan metalelogbon lo ti lugbadi arun naa nipinle meje to ti wo bayii.
Wednesday, 11 October 2017
Ijoba ipinle Osun ti dira ogun sile de arun Monkey Pox - Kusamotu
Tags
# iroyin
# iroyin-agbegbe
.Unknown
.
iroyin-agbegbe
Labels:
iroyin,
iroyin-agbegbe
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment