IROYIN YAJOYAJO

Wednesday, 11 October 2017

Latari aisan owo-ori; Aregbesola ti banki merin pa l'Osogbo

Tolulope Emmanuel, Osogbo

Ileese to n pawo wole labenu funjoba ipinle Osun, Osun State Internal Revenue Service ti ti ileefowopamo merin pa nilu Osogbo bayii latari pe won kuna lati sanwo ori.

Awon ileefowopamo naa ni Diamond Bank Plc, First City Monument Bank (FCMB) and Guaranty Trust Bank (GTB) ati Fidelity Bank plc.

Gege bi adele alaga IRS, Ogbeni Bucci Ali se wi, laarin odun 2012 si 2014 lawon ileefowopamo naa je owo to je milioonu lona mejilelaadorin naira.

Bucci ni awon banki naa yoo wa ni titipa titi digba ti won ba too san gbogbo owo ti won je ohun.



No comments:

Post a Comment