IROYIN YAJOYAJO

Sunday, 15 October 2017

L'Osun, awon osise ijoba fariga,won lawon o gba idaji owo osu mo


Tolulope Emmanuel, Osogbo

Leyin opolopo osu tawon osise ijoba nipinle Osun ti n gba idaji owo osu, o dabi eni pe oro naa ko fee wo laarin awon atijoba mo.

A ti gbo pe awon omo egbe naa ti fariga fun awon adari won, won si ti so pe eyi ti gbogbo aye mo awon si osise aafusa (half salary)  ti to ge.

Idi niyii ti awon adari egbe naa kaakiri ipinle Osun yoo fi sepade pajawiri kan nilu Osogbo lola nibi ti won yoo ti funjoba ipinle Osun ni gbedeke osu meji lati bere sii san ekunrere owo osu fun won.



Gege bi alaga egbe osise nipinle Osun, Jacob Adekomi se so, yala kijoba bere sii san owo osu osise fun won lekunrere, bere latinu osu kejila tabi kiyanselodi to lagbara bere nipinle Osun.

A oo ranti pe ko pe ti Gomina Aregbesola de ori aleefa leekeji loun atawon adari egbe osise ijoba jo sadehun pe kijoba maa san ekunrere owo osu fawon ipele Kinni si ikeje, nigba tawon to ku yoo maa gba idaji owo osu.

Adehun naa wa titi digba ti eto oro aje yoo fi rugogo sii sugbon awon osise ti yari bayii pe igba ti nnkan le lawon n gbo latodo ijoba, awon o gbo igba ti nnkan rorun rara.

No comments:

Post a Comment