IROYIN YAJOYAJO

Sunday, 15 October 2017

Ko le dun mo mi ninu ti oko mi ba feyawo le mi, sugbon... - Olori Oluwo


Tolulope Emmanuel, Osogbo

Olori Oluwo ti ilu Iwo, Chanel Chin ti so pe ko le je idunnu oun ti oko oun, Oba Abulrasheed Akanbi, Telu Kinni ba fe iyawo miin le oun.

Olori Chin ni bo tile je pe ko tii si ami pe oko oun fee feyawo le oun, ko si nnkan toun le se ti Kabiesi ba pinnu lati se bee.

Gege bo se wi "Asa won nibi ni, ko si nnkan ti mo le se. Loooto inu mi ko le dun, mi o kan tie ro pe Kabiesi fee se bee.

"Bo tile je pe asa won nibi ni sugbon gbogbo nnkan ti n yi pada. Iriri awon oniyawo pupo ti n fun igbeyawo oko-aya kan lagbara bayii, paapa bi olaju se n fojoojumo gbile".

No comments:

Post a Comment