Ayomide Sanni, Eko
Owo ileese olopa ipinle Eko ti te awon eleegun meji lori esun pe won n lo 'eku' lati ja awon araalu lole.
Lagbegbe Elere ni Agege lowo ti te awon ara-orun ohun.
Gege bi komisanna olopa nipinle Eko se wi, ko si odun eegun kankan to n waye lasiko naa, bee ni ko si oba kankan tabi awon elesin ibile ti won fun awon eeyan ohun lase lati gbe eegun jade.
O ni awon araalu ni won sare pe ileese awon pe se lawon eegun mejeeji ohun dede bo sita pelu awon janduku ti won jo fee sise ibi lojo naa.
O ni bi awon eegun ohun ba ti deruba awon eeyan lo niwaju lawon janduku ti won jo koworin yoo bere sii ko oja ninuu soobu onisoobu, ti won yoo si maa gbowo lowo awon eeyan.
Komisanna yii ni iwa palapala naa ti wa nipinle Eko ti pe sugbon asiko ti to bayii tileese olopa yoo dekun iwa naa.
O ni laipe ni awon ara-orun ohun pelu awon ti won n saaju won yoo foju bale ejo.
Thursday, 5 October 2017
Nnkan nla! Owo te awon 'ara-orun' to n jale l'Eko
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment