Tolulope Emmanuel, Osogbo
Sheik Qaasim Durojaye ti parowa si gbogbo awon omo orileede yii lati fimosokan ki Naijiria le goke agba.
Lasiko idanileko kan ti egbe The Muslim Congress sagbekale re fun ayeye odun ketadinlogota ominira orileede yii lo ti so pe ninu isokan nikan lawon erongba Allah forileede yii too le jo.
Sheik Durojaye ni a gbodo gboju aagan si ilu tituka ti awon kan n lu lorileede yii bayii nitori pe Allah nikan lo mo idi to fi da wa papo sojukan.
O waa ro gbogbo awon ti won di ipo mu lorileede yii lati sise pelu iberu Allah lokan won, ki won si rii pe awon araalu ri ere ijoba tiwantiwa je.
Ninu idanileko tire, Mufasir tilu Osogbo, Sheikh Maruf Idols tenumo pe o ti to akooko fun gbogbo awon omo orileede yii lati sunmo Allah ju ti tele lo, ki won si ko iwa ati isee re.
O ni a gbodo maa bere sii fi otito inu ba ara wa lo nitori nipase bee nikan ni iwa jegudujera yoo fi rokun igbagbe lorileede yii.
Lara awon ti won wa nibe lojo naa ni Olobaagun ti Obaagun, Oba Jimoh Adebisi, Imaamu agba ti Ido Osun, Sheik Abdulfatah Bolajoko, Senato Bayo Salami atawon miin.
Thursday, 5 October 2017
Ninu isokan nikan lorileede yii ti le goke agba - Sheik Durojaye
Tags
# iroyin
# iroyin-agbegbe
.Unknown
.
iroyin-agbegbe
Labels:
iroyin,
iroyin-agbegbe
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment