Gomina ipinle Kaduna, Nasir el-Rufai, ti so pe ko si enikeni to le da oun duro lati mase du ipo leekeji gege bii gomina ipinle naa.
Lasiko to n soro lori eto orii redio kan lo ti so pe niwon igba ti Aare Mohammed Buhari ti so fun oun pe ko si wahala kankan lona oun, oun ti mura tan lati dupo naa.
Elrufai ni leyin toun ba awon lookolooko ninu egbe oselu APC nipinle naa soro ti won si so pe koun tesiwaju loun gba odo Aare lo, ti Aare Buhari si so pe ko sewu.
O waa ni ipinnu oun ko da enikeni to ba tun nife ninu ipo naa duro ati pe idibo abele yoo wa gege bii ofin egbe naa.
No comments:
Post a Comment