Adeola Tijani, Ibadan
Kootu kokokoko ti Gbaremu lagbegbe Ijokodo nilu Ibadan ti tu igbeyawo olodun mesan to wa laarin Arabinrin Morufa Opeyemi ati oko re, Rafiu Opeyemi ka.
Se ni Morufa so fun ile ejo pe oun ko nifokanbale nile oko oun, o ni ojoojumo lawon maa n ja ati pe nigba toun too keru jade lodo e loun too nigbadun, idi si niyii toun fi pinnu lati ko o sile.
Leyin eyi ni Morufa ju bonbu oro pe kii se oko oun lo ni omo kerin to je abigbeyin oun.
Awon adajo kootu naa beere eni to bimo naa fun, Morufa ni baba kan to n ge bulooku toun si ti ba sise ri lo fun oun loyun nigba naa. O waa ro ile ejo pe ki won je ki oun maa mojuto awon omo meta toun bi fun Rafiu.
Ninu oro tire, okooyawo ni oun gan ti setan lati pin gaari pelu Morufa. O ni alagbere ponnbele ni ati pe oniruuru okunrin lo maa n gbe sun ninu ile toun ba ti ririnajo.
O ni oun fe kawon omo meteeta ti won je toun ninu awon omo naa wa lodo oun nitori oun setan lati toju won daada.
Nigba to n gbe idajo re kale, aare kootu naa, Ogbeni Edward Olalere Fadugba woye pe ko si ife kankan mo laarin awon tokotaya naa, o si tu igbeyawo naa ka pelu ase pe ki oko maa gbo bukata lorii ileewe ati ilera awon omo meteeta ohun.
Monday, 9 October 2017
Home
/
iroyin
/
iroyin-kootu
/
Kii se oko mi lo ni abigbeyin wa, baba onibulooku ni mo bii fun - Morufa
Kii se oko mi lo ni abigbeyin wa, baba onibulooku ni mo bii fun - Morufa
Tags
# iroyin
# iroyin-kootu
.Unknown
.
iroyin-kootu
Labels:
iroyin,
iroyin-kootu
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment