Tolulope Emmanuel, Osogbo
Egbe oselu PDP nipinle Osun ti rawo ebe si gomina ipinle yii tele, Omooba Olagunsoye Oyinlola pe ko forijin awon fun iwa ti won hu sii eleyii to mu un kuro ninu egbe naa.
Lasiko ti igbimo afunso ipinle Osun sabewo si Oyinlola nilu e, Okuku ni won ti so pe awon fee toro aforijin nitori pe ko seni ti ko mo pe iwa aidaa ni won hu sii nigba naa.
Igbimo naa, eleyii ti alaga won Alhaji Sarafadeen Ishola ko sodi pelu Erelu Olusola Obada ati Alhaji Lere Oyewumi so pe abewo awon kii se lati mu Oyinlola pada segbe PDP nitori awon gbodo bowo fun ipinnu re sugbon awon mo pe egbe oselu PDP se Oyinlola gidigidi, idi si niyii tawon fi gbodo tuuba lodo e.
Ninu oro re, Omooba Olagunsoye Oyinlola ni gbogbo igbiyanju loun se lati dena iyapa to pada sele ninu egbe naa sugbon ko so eso rere.
Oyinlola ni loooto ni ohun to sele nigba naa dun oun dokan sugbon pelu abewo awon eeyan ohun ati oro Olorun to pondandan idarijin, ohun ti dariji egbe naa.
O waa fi asiko naa dupe fun oro ti won so lori ipinnu oun lati darapo mo egbe APC, bee lo safihan awon asaaju egbe oselu APC ti won wa nijoko lojo naa han won
Tuesday, 3 October 2017
Otitoleke! PDP be Oyinlola, won ni ko forijin egbe awon
.Unknown
.
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment