Tolulope Emmanuel, Osogbo
Bo tile je pe ajo eleto idibo ijoba ibile nipinle Osun ti koko so pe oun ko tii setan fundibo, alaga ajo naa ti kede bayii pe ki gbogbo awon egbe oselu ti won ba fee kopa nibi idibo ohun bere iforukosile lodo awon.
Gege bi alaga ajo naa, Otunba Segun se fi sita, iforukosile gbogbo egbe oselu to ba fee kopa ni yoo fun ajo naa lanfaani lati seto to ye funpalemo idibo naa.
O ni ki gbogbo awon egbe oselu yoju si ofiisi ajo naa fun iforukosile bere lati ojo kerin titi di ojo kesan osu kewa yii.
Otunba Segun ni laarin aago mewa si aago merin irole ojoojumo leto naa yoo ma waye.
No comments:
Post a Comment