IROYIN YAJOYAJO

Wednesday, 25 October 2017

Owo te Korede atawon ore e ti won n se oogun aworo fawon asewo


Tolulope Emmanuel, Osogbo

Owo ileese olopa ipinle Eko ti te awon ore meta ti won n ta ose aworo fawon eeyan.

Awon meteeta ohun ni Korede Ojo, Ifedayo Ojo ati Akinola Faleke.

Gege bi adele komisanna funleese olopa nipinle naa, Imohimi Edgar se so, lagbegbe Folashade lorita Maruwa ni Lekki Phase 1 lowo ti te awon afurasi naa.

O ni adiye kan ti gbogbo araa re kun fun eje lawon ba ninuu yaara tawon eeyan ohun n lo bii ojubo ti won ti n se ose aworo naa.

Ninu oro Akinola Faleke, o ni bii egberun meta si marun naira lawon maa n gba lowo awon onibara awon ati pe se ni won a fi ose naa we ti aje a si maa bugba won.

Faleke ni latigba tawon ti n ta ose aworo naa, awon asewo lo po ju ninu awon onibara awon, ti won si maa n se daada.

Amo sa, Edgar ti ni laipe lawon eeyan ohun yoo foju bale ejo.


No comments:

Post a Comment