IROYIN YAJOYAJO

Thursday, 26 October 2017

Aje oo! Ogbon odun l'Osun yoo fi sanwo papako ofurufu MKO n'Ido-Osun

Tolulope Emmanuel, Osogbo

Gbogbo eto lo ti to bayii laarin ijoba ipinle Osun atileese Awol International Company lati pari papako ofurufu MKO Abiola to wa ni Ido Osun.

Bilioonu lona mokandinlogorin naira ni won jo sadehun bayii, odidi ogbon odun gbako si ni Awol yoo fi lo o ko too gbe e sile funjoba

A oo ranti pe bilioonu merin ataabo nijoba Gomina Aregbesola koko  kede pe awon fee na lori papako ofurufu naa

Nigba to ya ni won so pe bilioonu mokanla lawon yoo na.

Bee ijoba ti na bilioonu meta ataabo naira le e lori ko too di pe won ni agbara awon ko ka mo bayii ti won si gbe e jade lowo  nla naa.

No comments:

Post a Comment