Asiri ohun to da wahala sile laarin Gomina ipinle Eko, Akinwumi Ambode ati Onorebu Funmi Tejuosho ti han bayii.
A gbo pe ile to je alabala marun 5 bedroom to wa lojule keta, opopona Sasegbon ni Ikeja GRA nilu Eko lo je ile tijoba seto fun enikeni to ba je igbakeji abenugan ile igbimo asofin ipinle Eko.
Odun 2010 ti Onorebu Tejuosho je igbakeji abenugan ile la gbo pe o ko denu ile naa sugbon latigba ti won ti ye aga mo on nidi lo ti yari kanle pe oun ko nii kuro ninu ile naa.
Iwadi tun fi han pe dipo ki Onorebu Tejuosho kuro ninu ile ijoba naa, o loo lo oruko ileese re Debam Mega Solutions Limited lati ra ile naa ni milioonu lona ogun naira nigba yen.
Gbogbo ona la gbo pe Gomina Raji Fashola ati Onorebu Ikuforiji gba lati je ki onorebu yii kuro ninu ile naa sugbon ti ko so eso rere, ko si fun awon igbakeji abenugan ti won ti n je latigba naa lanfaani lati lo ile ohun.
Idi niyen ti awon omo ile igbimo asofin asiko yii fi pon on ni dandan fun Gomina Ambode lati gba ile naa atawon miin ti won ta nitakuta fawon araalu.
Monday, 6 November 2017
Home
/
iroyin
/
iroyin-agbegbe
/
iroyin-oselu
/
Abajo! E wo ohun to da wahala sile laarin Ambode ati Tejuosho
Abajo! E wo ohun to da wahala sile laarin Ambode ati Tejuosho
Tags
# iroyin
# iroyin-agbegbe
.Njeetigbo
.
iroyin-oselu
Labels:
iroyin,
iroyin-agbegbe,
iroyin-oselu
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment