Tolulope Emmanuel, Osogbo
Inu idaamu ni baba eni odun metalelaadota kan, Thomas Oghenede wa bayii pelu bi awon afurasi meji to soniduro fun ti se na papa bora, ti won ko si yoju sile ejo.
Esun jibiti lilu ati didogbon gba owo ni won fi kan Uche Portia ati Thomas Godspower, owo naa si je milioonu marun naira.
Nigba ti won ko awon afurasi ohun lojo kejo osu kesan odun yii lo si ofiisi Area Commander awon olopa ni Moore nilu Ileefe ni nnkan aago merin irole, nibe ni Thomas Oghenede soniduro fun won pelu ileri pe wom ko nii salo nigbakuugba ti won ba fee lo si kootu.
Inspekito Sunday Osanyintuyi to n soju ileese olopa lori esun naa salaye pe leyin tawon olopa tu awon afurasi mejeeji ohun sile ni won ti juba ehoro, ti enikeni ko si gburo won mo, koda won ko yoju lojo to ye ki won wa si kootu.
O ni iwa ti okunrin naa hu lodi, bee lo si nijiya labe ofin iwa odaran abala kerindinlaadoje ati iketadinlaadoje tipinle Osun ti odun 2002.
Nigba ti won ka esun naa si olujejo leti, o ni oun ko jebi re, bee ni agbejoro re, Ben Adirieje ro ile ejo lati faaye beeli sile fun un lona irorun ati pe ko nii salo fun igbejo.
Ninu idajo re, Majistreeti Risikat Olayemi faaye beeli sile fun olujejo pelu egberun lona eedegbeta naira ati oniduro kan ni iye kannaa. O ni oniduro naa gbodo ni ile (land) lagbegbe kootu, o si gbodo maa gbe lagbegbe naa pelu.
Leyin naa lo sun igbejo siwaju di ojo kokanla osu kokanla odun yii.
No comments:
Post a Comment