Tolulope Emmanuel, Osogbo
Ni imurasile fun idibo sile igbimo asofin agba orileede yii ti yoo waye lodun 2019, iwadi ti fihan bayii pe oro eni ti yoo je oludije labe egbe oselu APC lati ekun Ife/ Ijesa ti n fa awuyewuye bayii.
Arigbamu iroyin fidii re mule pe bi Gomina Rauf Aregbesola se n gbaradi lati dupo naa ni komisanna re feto isuna nigba kan, Dokita Wale Bolorunduro naa ti bere ipolongo labenu funpo naa.
Idameta ninu idamerin awon agbaagba ninu egbe oselu APC lati ekun naa la gbo pe won wa leyin Bolorunduro nigba ti olori awon omo ile to poju nile igbimo asofin ipinle yii, Timothy Owoeye naa n ja raburabu lati rii pe tikeeti naa bo si Aregbesola lowo.
Niwon igba ti Seneto Jide Omoworaare ti lo odun mejo nipo naa, igbagbo gbogbo awon egbe oselu to ku ni pe ile Ijesa lo ku ti ipo naa yoo lo.
Bo tile je pe aheso ti n lo lori erongba awon kan lati lo Aregbesola lekun Alimosho nipinle Eko gege bii Seneto, a gbo pe arumoje lasan ni ati pe agbegbe Ife/Ijesa lo nife lati soju nile igbimo asofin agba.
Gege bi omo egbe oselu APC kan lati agbegbe naa to ni ka foruko bo oun lasiri se so, opolopo awon agbaagba ni won ti seleri lati tele Bolorunduro ko too di pe Aregbesola so pe oun yoo tun se Seneto leyin odun mejo lori ipo gomina.
A gbo pe opolopo igbese lo ti n lo labenu bayii lati ba Wale Bolorunduro soro pe ko yonda ipo naa fun Aregbesola sugbon ti awon alatileyin re n fi aake kori.
Bee a gbo pe Gomina Aregbesola naa ko fee fagidi mu oro naa latari opolopo iranlowo ti Bolorunduro se fun un nigba to je komisanna, paapa, oniruuru eyawo ti won fi n se ise akanse.
Bi ohun gbogbo ba wa se n lo lati ekun Ife/Ijesa la o fi maa to yin leti.
No comments:
Post a Comment