IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 7 November 2017

Won ti sinku Lawrenta, akeko Poli ti ibon figilante pa

Beeyan ba je ori ahun, to ba de ibi isinku omobinrin akekojade ileewe gbogbonise ilu Auchi, Uloko Lawrenta Apaume, se lomi yoo maa da poroporo loju e.
Ose meji seyin la gbo pe Lawrenta pari idanwo asekagba HND re, oun atawon egbe re si pinnu lati se ayeye pe awon pari layo ninu ile to n gbe.
Lati le pese aabo fawon akekojade yii, a gbo pe lanloodu ile awon Lawrenta ranse pe awon figilante lati wa maa so won.
Nigba ti ayeye yii wora daada, ti awon akekojade yii si n gbadun araa won lawon figilante naa bere sii yinbon soke lati dawoodunnu pelu awon omo yii sugbon ota ibon fo yo, deede ibi ti Lawrenta wa lo gba lo, kawon eeyan si too mo nnkan to n sele, omobinrin arewa yii ti je Olorun nipe.
Okan lara awon oreminu Lawrenta sapejuwe re gege bii oniwatutu ati pe ireti re ni lati lo fun eto agunbaniro re.
Amo sa, ileese olopa ipinle naa ti bere iwadi lori iku aitojo to pa omo naa.

No comments:

Post a Comment