Tolulope Emmanuel, Osogbo
Wosilat Oroki, Lateef Olagbaju ati Otun Eluremi ni won ti foju bale ejo majistreeti ilu Ileefe bayii lori esun pe won dawojo lu omokunrun kan.
Esun meji otooto to nii se pelu ikoluni ati idunkoko mo emi eni ni won fi kan awon olujejo meteeta yii.
Sajenti Sunday Osanyintuyi salaye funle ejo pe se lawon olujejo naa dena de Isiaka Olagbaju lojo kewa osu kewa odun yii nibi ti won ti dana iya fun un.
Lagbegbe Orelowo ni Ilode nilu Ileefe nisele naa ti waye. Osanyintuyi ni won na Isiaka, bee ni won si tun faso re ya eleyii to ni o nijiya labe ofin iwa odaran tipinle Osun.
Ninu atotonu tire, agbejoro fawon olujejo, Arabinrin Toyin Lawal-Olatunji ro ile ejo lati faaye beeli sile fun awon olujejo lona irorun pelu ileri pe won ko nii salo fun igbejo.
Nigba to n gbe idajo re kale, Majistreeti Olalekan Ijiyode faaye beeli sile fun okookan awon olujejo pelu egberun lona aadota naira ati oniduro kookan ni iye kannaa.
Leyin naa lo sun igbejo siwaju di ojo ketadinlogun osu kokanla odun yii.
No comments:
Post a Comment