Tolulope Emmanuel, Osogbo
Aare Osun New Era Lions Club, Oluomo Sunday Akere ti so pe egbe naa ko nii reyin ninuu ojuse re nipa kikun ijoba lowo fun igbe aye irorun awon araalu.
Ni kete ti Oluomo Akere gba ipo lo so pe ijoba nikan ko le da yanju oniruuru isoro to n koju awon araalu lasiko yii, idi niyen ti awon egbe alaanu gbogbo fi gbodo dide lati kun ijoba lowo.
O ni ohun akooko tawon fee se ni ayewo oju lofe fawon ti oju n yo lenu pelu ipese dingi lofe fun awon ti won nilo re.
Akere fi kun oro re pe egbe Lions Club yoo maa pin ounje fawon araalu loorekoore lati le din ebi ku laarin ilu.
Bakan naa lo ni awon ti pari gbogbo eto lati gbe kanga omi sawon ileewe ijoba kaakiri ipinle Osun lati le pese omi to see mu fawon omoleewe.
Gomina agbegbe 404 B2 fegbe naa, Lion Ayoola Samuel so pe ogorun odun seyin ni egbe naa ti n pese oniruuru nnkan amayederun fawon araalu ati pe awon tun mura sii lati tesiwaju.
O waa ro gbogbo awon ti ori segi ola fun lati darapo mo egbe naa fun igbesoke awon ti won ko rowo hori.
No comments:
Post a Comment