IROYIN YAJOYAJO

Monday, 6 November 2017

Haa! E wo iye ti Rochas Okorocha fee na lori igi keresimesi



Egbe kan toruko re n je G42 Imo Liberation Forum ti ke gbajare bayii pe milioonu lona otalegberin naira (#850m) nijoba ipinle Imo n mura lati fi ri igi keresimesi mole ni olu ilu ipinle naa.

Egbe naa ni bi Gomina Rochas Okorocha se n se owo oogun oju awon eeyan ipinle naa basubasu bayii to apero gbogbo omo orileede yii.

Gege bi adari eto iroyin egbe naa, Dokita Walter Duru se wi, pelu gbogbo ariwo tawon eeyan pa lorii milioonu lona eedegbeta naira ti Okorochas fi gbe ere Aare Jacob Zuma ti orileede South Afrika silu Owerri, sibe gomina naa ko dekun ina apa.

O ni aimoye owo osu ati owo ajemonu ni gomina ohun je awon osise ipinle Imo, sibe arigbamu iroyin tun fidii re mule pe o fee na #850m lori igi keresi.

G42 ni ebi opagbafowomeke lo n pa awon eeyan ipinle naa, bee ni awon Osisefeyinti ko ri eto won gba lowo ijoba Okorochas.

O waa ke si gbogbo awon omo orileede yii lati ba Okorochas soro, ko le mo pe adanwo ni ipo to wa, o si gbodo dekun lilo owo-ori awon araalu bo se wu u.

No comments:

Post a Comment