IROYIN YAJOYAJO

Monday, 6 November 2017

Owo te awon darandaran meji ti won pa Taye l'Abeokuta


Idayat Adigun, Abeokuta

Owo ileese olopa ipinle Ogun ti te awon darandaran meji nilu Abeokuta lori esun pe won ji akeegbe won kan gbe, ti won si gbemi e.

Gege bi alukoro funleese olopa ipinle naa, Abimbola Oyeyemi se wi, ojo ketalelogun osu kewa odun yii ni Hassan Amodu ati Abubakar Abdullahi ji Taye Amodu gbe, ti won si pa a.

Ohun tawon mejeeji so pe Taye se ni pe o ji maalu mejo lara awon maalu awon, idi niyii ti won fi gbe e, ti won si pa a lagbegbe Obada Oko nilu Abeokuta.

Nigba tawon kan fi isele naa to awon olopa leti, owo te awon eeyan mejeeji ninu igbo kijikiji kan lagbegbe Imeko ti won sa pamo si, won si ba ibon kan pelu ada meji lowoo won.

Won jewo pe lasiko ti Taye n ba awon ja lo ku, ti awon si sinku sinu iho nla kan nibe, bee ni won si ji gbogbo maalu re.

No comments:

Post a Comment