IROYIN YAJOYAJO

Monday, 6 November 2017

Opolopo ota ni won yi mi ka - Zaynab, Olori Ooni tele


Tolulope Emmanuel, Osogbo

Olori tele fun Ooni Adeyeye Enitan Ogunwusi, Zaynab Otiti ti pariwo sita pe opolopo ni awon ota ti won yi oun kaakiri sugbon inunibini won lo dabii agbara toun n lo lati tesiwaju.

Ninu oro kan ti Otiti ko sori ero ayelujara Instagramu re lo ti ni pupo ninu awon eeyan ni won kan n sedajo irinajo aye oun lai beere bi oro se je.

Gege bo se wi "Awon alaheso ni won n fun mi niwuri ati agbara lati tesiwaju laye. Opo ti oye ko ye ni won n da mi lebi irinajo aye mi. Eeyan nilo lati nigbagbo ninuu araa re lati le mu iyipada wa. Koda, bi ko ba si enikeni nihaa re. Awon abanije re je ara awon ona ti Olorun fee lo lati mu o debi giga laye.
-Ololajulo"

No comments:

Post a Comment