IROYIN YAJOYAJO

Monday, 6 November 2017

Nitori obinrin, Isaiah ge Emmanuel leti je, ladajo ba ju sewon odun marun


Tolulope Emmanuel, Osogbo

Adajo ile ejo giga ipinle Osun to wa nilu Ileefe ti ran Ogbeni Olaniyan Isaiah sewon odun marun gbako pelu ise asekara.

Se ni Isaiah loo gbe ija ka okunrin kan, Alonge Emmanuel molee re lojo ketadinlogbon osu keje odun 2015 lagbegbe Bolaji Olufunmi nilu Ipetumodu.

Won ni Isaiah fura pe o see se ko je pe ife ikoko wa laarin okunrin naa, Emmanuel ati iyawo oun to ti ko jade nile, idi niyen to fi loo gbe irin ba a nile.

O jalekun wole, o si bere sii le Emmanuel kaakiri, nigba to rii mu, o ge eti e je, o si se e lese yannayanna.

Esun meta otooto to nii se pelu igbiyanju lati paniyan, sise eeyan lese ni won fi kan Isaiah.

Ogbeni Bamidele Salawu to je agbejoro ijoba ni awon esun naa nijiya labe ofin.

Leyin opolopo atotonu, Onidajo Siyanbola pase pe ki Isaiah loo faso penpe roko oba fodidi odun marun gbako.

No comments:

Post a Comment