Tolulope Emmanuel, Osogbo
Dauda Olanipekun, eni odun metalelogoji ti kawo ponyin rojo nile ejo majistreeti kan nilu Ileefe lose to koja lori esun pe won ka eru ole mo on lowo.
Dauda la gbo pe won ka foonu Nokia 201 mo lowo eleyii ti enikan ti won n pe ni Bisi Olawole ji.
Gege bi agbejoro awon olopa lori esun naa, Inspekito Sunday Osanyintuyi se salaye fun kootu, nnkan aago marun aabo idaji ojo ketadinlogbon osu kejo odun yii ni won ka foonu naa mo Dauda lowo.
Osanyintuyi ni foonu Nokia ohun, ti iye owo re to egberun lona meedogbon naira lo je ti Ogbeni Ayo Okekunle sugbon ti won ba a lowo Dauda lagbegbe Sabo nilu Ileefe.
Nigba ti won ka esun ole jija ti won fi kan olujejo sii leti, o ni oun ko jebi esun naa.
Nitori idi eyi, adajo majistreeti ohun, Risikat Olayemi faaye beeli sile fun un pelu egberun lona ogun naira ati oniduro kan ni iye kannaa.
Olayemi ni oniduro naa gbodo je molebi olujejo to n gbe lagbegbe kootu ati pe o gbodo ni iwe idanimo orileede Naijiria pelu adireesi tawon olopa gbodo mo.
Leyin naa ladajo sun igbejo siwaju di osu kokanla odun yii.
No comments:
Post a Comment